*COD & Shipping Charges may apply on certain items.
Review final details at checkout.
₹1254
₹1331
5% OFF
Paperback
All inclusive*
Qty:
1
About The Book
Description
Author
A bí Adéọlá Ọrẹolúwa Adéfẹ̀sọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó ṣe èwe rẹ̀ nínú ayọ̀ àti ìdùnnú. Àwọn òbí rẹ̀ àgbà ní ìdílé ìyá ló tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú ìfẹ́ tó wàyàmì àti ẹ̀kọ́ ìwé tó yè kooro òun náà sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin agbègbè ibẹ̀. Ṣùgbọ́n nǹkan yí bìrí nígbà tí ó kó sí wàhálà abẹ́ ilé látàrí ìjìyà tí ó ń rí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Inú làásìgbò ìjìyà ara àti ọkàn yìí ló wà tí ó fi pàdánù àwọn ìbejì ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì tí ó bí ní kògbókògbó.Nínú ọdún 2019 ọmọkùnrin rẹ̀ àbísìkejì tí ó fìgbà kan jẹ́ ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà tún pa ara rẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni Adéọlá tún rí àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí ọkọ rẹ̀ kọ nípa rẹ̀ sí orí ẹ̀rọ ayélujára kà dé ibi pé òun lòun fa ikú ọmọ àwọn ọ̀hún.Ìrora ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ Adéọlá fara hàn kedere nínú ìtàn àgbọ́gbárímú yìí tí ó gbé kalẹ̀ ní ìrètí pé yóò dé etígbọ̀ọ́ àwọn tí yóò wúlò fún.Nínú ìwé yìí Adéọlá gbé ìtàn akíkanjú obìnrin kan tí ó dojú kọ wàhálà abẹ́le kalẹ̀. Lẹ́yìn-ò-rẹyìn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ó jáwé olúborí. Iloh Friday Okechukwu (Ph. D)