Ó jẹ́ ohùn ìdùnnú fún mí púpọ̀ láti kọ ìwé àkójọpọ̀ ewì yìí. A kọ ìwé ewì yìí ni àsìkò tí orílẹ̀-èdè Nàíjíríà pé Ọgọ́ta Ọdún láti șe àyàjọ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀ náà; ti wón șe ÀṢEYỌRÍ ÒMÌNIRA ỌGỌTA ỌDÚN ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÍJÍRÍÀ. Àwọn ewì jẹ ohun àbálàye tí ó jẹ ọmọ Yorùbá lógún. Ní ayé àtijọ́ ní ilè Yorùbá ò un ni àwọn bàbá-ńlá wa máa ń lò fún ìmọ̀ ìmọ̀ràn àti ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n won kìí kọọ́ sílẹ̀ nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀ mọ̀ọ́kọ–mọ̀ọ́kà rárá. Orísírísí ewì ni ó wa orísírísí ọ̀nà ni a sì lè pín ewì sí. Èrò ọkàn mí ní pé a ó gbàdùn ìwé àkójọpọ̀ ewì yìí. Sọ̀rọ̀ Sókè! ni àkọlé Ìwé Ìṣípayá Ewi Yorùbá yìí (Speak Up!). Àkọlé ìwé yìí jẹ jáde nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Nàíjíríà (A popular phrase that has informally become the name of the millennial slang of generations in Nigeria). Àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìwọde #EndSARS ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà: ní ìpínlè Èkó Ekiti Ọ̀yọ́ Ondo Osun Kwara ati Abuja lati bá àwọn olórí àti àwọn ọmọ ilu sọ̀rọ̀ ní ọdún 2020. Kí ni ìtumọ̀ Sọ̀rọ̀ Sókè àti Ìwọ́de tí àwọn ọ̀dọ́ n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yìí? Wọ́n fi Ìwọ́de #EndSARS yìí sọ pé kí àwọn Ọlọpa má ṣe pa àwọn ará ìlú mọ́ pàtàkì jù lọ àwọn ọ̀dọ́ àti pé kí olúkúlùkù sọ àwọn ẹ̀dùn ọkàn wọn gbogbo jáde ni orílẹ̀-èdè NÀÍJÍRÍÀ.
Piracy-free
Assured Quality
Secure Transactions
Delivery Options
Please enter pincode to check delivery time.
*COD & Shipping Charges may apply on certain items.